Daniel 7:1-6

Daniẹli lá àlá ẹranko mẹ́rin

1Ní ọdún àkọ́kọ́ Belṣassari ọba Babeli, Daniẹli lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe sùn sórí ibùsùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.

2Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè. 3 a , bẸranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà.

4 c“Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

5“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’

6“Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.

Copyright information for YorBMYO